Daniel 4:12-21

12 aEwé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

13“Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run 14ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. 15Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí koríko igbó.

“ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrín ilẹ̀ ayé.
16Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.

17“ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’

18“Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”

Daniẹli túmọ̀ àlá náà

19Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.”

Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ:
20Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè ààyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run. 21Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èso rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko igbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn.
Copyright information for YorBMYO